51 Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì ṣá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.
52 Jésù wí fún un pé, “Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni.
53 Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) ańgẹ́lì méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹsẹ̀kẹsẹ̀.
54 Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsìn yìí?”
55 Nígbà náà ni Jésù wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Tàbí èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹ̀ḿpìlì, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.
56 Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan-an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sá lọ.
57 Àwọn tí ó mú Jésù fà á lọ sí ilé Káíáfà, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olúkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbààgbà Júù péjọ sí.