57 Àwọn tí ó mú Jésù fà á lọ sí ilé Káíáfà, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olúkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbààgbà Júù péjọ sí.
58 Ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jésù.
59 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù pé jọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jésù, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un.
60 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde.
61 Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘èmi lágbára láti wó tẹ̀ḿpìlì Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”
62 Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jésù pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?”
63 Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́ rọ́rọ́.Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kírísítì Ọmọ Ọlọ́run.”