56 Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Màríà Magidalénì, àti Màríà ìyá Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, àti ìyá àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
57 Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatíyà, tí à ń pè ní Jósẹ́fù, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù,
58 lọ sọ́dọ̀ Pílátù, ó sì tọrọ òkú Jésù. Pílátù sì pàṣẹ kí a gbé é fún un.
59 Jósẹ́fù sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í.
60 Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnraa rẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ.
61 Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wà níbẹ̀, wọn jòkóò dojú kọ ibojì náà.
62 Lọjọ́ kejì tí ó tẹlé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ sọ́dọ̀ Pílátù.