1 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Máríà Magidalénì àti Màríà kejì lọ sí ibojì.
2 Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí ańgẹ́lì Olúwa ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí.
3 Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
4 Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wá rìrì wọn sì dàbí òkú.