1 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Máríà Magidalénì àti Màríà kejì lọ sí ibojì.
2 Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí ańgẹ́lì Olúwa ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí.
3 Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
4 Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wá rìrì wọn sì dàbí òkú.
5 Nígbà náà ni ańgẹ́lì náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jésù tí a kàn mọ́ àgbélébùú.
6 Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí.
7 Nísinsìn yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Gálílì síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóògbé rí i, wò ó, o ti sọ fún yin”.