25 “Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídajọ lọ́wọ́, onídájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀sọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú.
26 Lóòótọ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títítí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.
27 “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’
28 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìrinrin kan ní ìwòkuwò, ti bà a ṣe panṣágà ná ní ọkàn rẹ̀.
29 Bí ojú rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́sẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sínú iná ọ̀run àpáàdì.
30 Bí ọwọ́ rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀ gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé ju kí gbogbo ara rẹ lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì.
31 “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ gbọdọ̀ fún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’