1 “Ẹ kíyè ṣára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò lérè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run.
2 “Nítorí náà, nígbà ti ẹ ń bá ti fún aláìní, ẹ má ṣe fi kàkàkí kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní sínágọ́gù àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún.
3 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ńfi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe,
4 kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mímọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun tí ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ.