17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá gbààwẹ̀, bu òróró sí orí rẹ, kí ó sì tún ojú rẹ ṣe dáradárá
18 Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sìí Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ.
19 “Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le dípẹtà àti ibi tí àwọn olèlè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ.
20 Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti ji í lọ.
21 Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú.
22 “Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀.
23 Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wáá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó!