16 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn olókùnrùn láradá.
17 Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:“Òun tikara rẹ̀ gbà àìlera wa,ó sì ń ru àrùn wa.”
18 Nígbà tí Jésù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n sọdá sí òdìkejì adágún.
19 Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
20 Jésù dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀lọ̀kọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
21 Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú bàbá mi ná.”
22 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”