Kronika Keji 14:8-14 BM

8 Asa ọba ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ọmọ ogun ní ilẹ̀ Juda, tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀ ati ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) láti Bẹnjamini tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọrun. Gbogbo wọn ni a ti kọ́ ní ogun jíjà tí wọ́n sì jẹ́ akọni.

9 Sera, ará Etiopia, gbógun tì wọ́n pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun (1,000,000) ọmọ ogun ati ọọdunrun (300) kẹ̀kẹ́ ogun. Wọ́n sì jagun títí dé Mareṣa.

10 Asa jáde lọ láti bá a jà. Olukuluku tẹ́ ibùdó ogun rẹ̀ sí àfonífojì Sefata ní Mareṣa.

11 Asa ké pe OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kò sí olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ nítorí pé o lè ran àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lágbára lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn tí wọ́n lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLUWA Ọlọrun wa, nítorí pé ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ní orúkọ rẹ ni a jáde láti wá bá ogun ńlá yìí jà. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun wa, má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣẹgun rẹ.”

12 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun àwọn ará Etiopia fún Asa ati àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Etiopia sì sá.

13 Asa ati àwọn ogun rẹ̀ lé wọn títí dé Gerari. Ọpọlọpọ àwọn ará Etiopia sì kú tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè gbá ara wọn jọ mọ́; wọn sì parun patapata níwájú OLUWA ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Juda sì kó ọpọlọpọ ìkógun.

14 Wọ́n run gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè Gerari, nítorí pé ẹ̀rù OLUWA ba àwọn ará ibẹ̀. Wọ́n fi ogun kó gbogbo àwọn ìlú náà nítorí pé ìkógun pọ̀ ninu wọn.