17 Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣé o ranti pé mo ti sọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún mi rí? Àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nìkan ni òun máa ń sọ.”
18 Mikaya bá dáhùn pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Mo rí OLUWA, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, àwọn ogun ọ̀run sì wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì rẹ̀.
19 OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu, ọba Israẹli, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi, kí ó sì kú níbẹ̀.’ Bí àwọn kan tí ń sọ nǹkankan, ni àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn.
20 Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’
21 Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ”
22 Mikaya ní, “OLUWA ni ó mú kí àwọn wolii rẹ wọnyi máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, ṣugbọn àjálù burúkú ni OLUWA ti pinnu pé yóo dé bá ọ.”
23 Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?”