1 NIGBANA li OLUWA wi fun mi pe, Gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju, ki o si tọ̀ mi wá lori òke na, ki o si ṣe apoti igi kan.
2 Emi o si kọ ọ̀rọ ti o ti wà lara walã iṣaju ti iwọ fọ́, sara walã wọnyi, iwọ o si fi wọn sinu apoti na.
3 Emi si ṣe apoti igi ṣittimu kan, mo si gbẹ́ walã okuta meji bi ti isaju, mo si lọ sori òke na, walã mejeji si wà li ọwọ́ mi.
4 On si kọ ofin mẹwẹwa sara walã wọnni, gẹgẹ bi o ti kọ ti iṣaju, ti OLUWA sọ fun nyin lori òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì; OLUWA si fi wọn fun mi.
5 Mo si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke na wá, mo si fi walã wọnni sinu apoti ti mo ti ṣe; nwọn si wà nibẹ̀, bi OLUWA ti paṣẹ fun mi.
6 (Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati Beerotu ti iṣe ti awọn ọmọ Jaakani lọ si Mosera: nibẹ̀ li Aaroni gbé kú, nibẹ̀ li a si sin i; Eleasari ọmọ rẹ̀ si nṣe iṣẹ alufa ni ipò rẹ̀.