8 Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi.
9 Nitorina ni Lefi kò ṣe ní ipín tabi iní pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; OLUWA ni iní rẹ̀, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun ti ṣe ileri fun u.)
10 Emi si duro lori òke na, gẹgẹ bi ìgba iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru: OLUWA si gbọ́ ti emi ni igbana pẹlu, OLUWA kò si fẹ́ run ọ.
11 OLUWA si wi fun mi pe, Dide, mú ọ̀na ìrin rẹ niwaju awọn enia, ki nwọn ki o le wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki nwọn ki o le gbà ilẹ na, ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.
12 Njẹ nisisiyi, Israeli, kini OLUWA Ọlọrun rẹ mbère lọdọ rẹ, bikoṣe lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, lati ma fẹ́ ẹ, ati lati ma sìn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo,
13 Lati ma pa ofin OLUWA mọ́, ati ìlana rẹ̀, ti mo filelẹ fun ọ li aṣẹ li oni, fun ire rẹ?
14 Kiyesi i, ti OLUWA Ọlọrun rẹ li ọrun, ati ọrun dé ọrun, aiye pẹlu, ti on ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.