1 LẸHIN ọdún mejemeje ni ki iwọ ki o ma ṣe ijọwọlọwọ.
2 Ọ̀na ijọwọlọwọ na si li eyi: gbogbo onigbese ti o wín ẹnikeji rẹ̀ ni nkan ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ; ki o ma ṣe fi agbara bère rẹ̀ lọwọ ẹnikeji rẹ̀, tabi lọwọ arakunrin rẹ̀; nitoriti a pè e ni ijọwọlọwọ OLUWA.
3 Iwọ le fi agbara bère lọwọ alejò: ṣugbọn eyiti ṣe tirẹ ti mbẹ li ọwọ́ arakunrin rẹ, ni ki iwọ ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ.
4 Ṣugbọn ki yio sí talaka ninu nyin; (nitoripe OLUWA yio busi i fun ọ pupọ̀ ni ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati gbà a;)
5 Kìki bi iwọ ba fi ifarabalẹ fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi gbogbo ofin yi, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni lati ṣe.
6 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ, bi o ti ṣe ileri fun ọ: iwọ o si ma wín ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn iwọ ki yio tọrọ; iwọ o si ma ṣe olori ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn nwọn ki yio ṣe olori rẹ.
7 Bi talakà kan ba mbẹ ninu nyin, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ, ninu ibode rẹ kan, ni ilẹ rẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe mu àiya rẹ le si i, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe há ọwọ́ rẹ si talakà arakunrin rẹ: