14 Nitori orilẹ-ède wọnyi ti iwọ o gbà, nwọn fetisi awọn alakiyesi-ìgba, ati si awọn alafọ̀ṣẹ: ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni, OLUWA Ọlọrun rẹ kò gbà fun ọ bẹ̃.
15 OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi;
16 Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú.
17 OLUWA si wi fun mi pe, Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ.
18 Emi o gbé wolĩ kan dide fun wọn lãrin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọ̀rọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ.
19 Yio si ṣe, ẹniti kò ba fetisi ọ̀rọ mi ti on o ma sọ li orukọ mi, emi o bère lọwọ rẹ̀.
20 Ṣugbọn wolĩ na, ti o kùgbu sọ ọ̀rọ kan li orukọ mi, ti emi kò fi fun u li aṣẹ lati sọ, tabi ti o sọ̀rọ li orukọ ọlọrun miran, ani wolĩ na yio kú.