2 Bi arakunrin rẹ kò ba si sí nitosi rẹ, tabi bi iwọ kò ba mọ̀ ọ, njẹ ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ, ki o si wà lọdọ rẹ titi arakunrin rẹ yio fi wá a wá, ki iwọ ki o si fun u pada.
3 Bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o si ṣe si gbogbo ohun ninù arakunrin rẹ, ti o nù lọwọ rẹ̀, ti iwọ si ri: ki iwọ ki o máṣe mú oju rẹ kuro.
4 Iwọ kò gbọdọ ri kẹtẹkẹtẹ tabi akọ-malu arakunrin rẹ ki o ṣubu li ọ̀na, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn: iwọ o si ràn a lọwọ nitõtọ lati gbé e dide.
5 Obinrin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ̀, bẹ̃li ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obinrin wọ̀: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bẹ̃ irira ni nwọn si OLUWA Ọlọrun rẹ.
6 Bi iwọ ba bá itẹ́ ẹiyẹ kan pade lori igi kan, tabi ni ilẹ, ti o ní ọmọ tabi ẹyin, ti iya si bà lé ọmọ tabi lé ẹyin na, iwọ kò gbọdọ kó iya pẹlu ọmọ:
7 Bikoṣe ki iwọ ki o jọwọ iya lọwọ lọ, ki iwọ ki o si kó ọmọ fun ara rẹ; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ.
8 Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu.