4 Nitoriti nwọn kò fi omi pẹlu onjẹ pade nyin li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti Egipti jade wá; ati nitoriti nwọn bẹ̀wẹ Balaamu ọmọ Beori ara Petori ti Mesopotamia si ọ, lati fi ọ bú.
5 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; OLUWA Ọlọrun rẹ si yi egún na pada si ibukún fun ọ, nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ fẹ́ ọ.
6 Iwọ kò gbọdọ wá alafia wọn tabi ire wọn li ọjọ́ rẹ gbogbo lailai.
7 Iwọ kò gbọdọ korira ara Edomu kan; nitoripe arakunrin rẹ ni iṣe: iwọ kò gbọdọ korira ara Egipti kan; nitoripe iwọ ti ṣe alejò ni ilẹ rẹ̀.
8 Awọn ọmọ ti a bi fun wọn yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA ni iran kẹta wọn.
9 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o pa ara rẹ mọ́ kuro ninu ohun buburu gbogbo.
10 Bi ọkunrin kan ba wà ninu nyin, ti o ṣèsi di aimọ́ li oru, njẹ ki o jade lọ sẹhin ibudó, ki o máṣe wá ãrin ibudó: