7 Iwọ kò gbọdọ korira ara Edomu kan; nitoripe arakunrin rẹ ni iṣe: iwọ kò gbọdọ korira ara Egipti kan; nitoripe iwọ ti ṣe alejò ni ilẹ rẹ̀.
8 Awọn ọmọ ti a bi fun wọn yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA ni iran kẹta wọn.
9 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o pa ara rẹ mọ́ kuro ninu ohun buburu gbogbo.
10 Bi ọkunrin kan ba wà ninu nyin, ti o ṣèsi di aimọ́ li oru, njẹ ki o jade lọ sẹhin ibudó, ki o máṣe wá ãrin ibudó:
11 Yio si ṣe, nigbati alẹ ba lẹ, ki on ki o fi omi wẹ̀ ara rẹ̀: nigbati õrùn ba si wọ̀, ki o ma bọ̀wá sãrin ibudó.
12 Ki iwọ ki o ní ibi kan pẹlu lẹhin ibudó, nibiti iwọ o ma jade lọ si:
13 Ki iwọ ki o si ní ìwalẹ kan pẹlu ohun-ìja rẹ; yio si ṣe, nigbati iwọ o ba gbọnsẹ lẹhin ibudó, ki iwọ ki o fi wàlẹ, ki iwọ ki o si yipada, ki o bò ohun ti o ti ara rẹ jade: