57 Ati si ọmọ-ọwọ rẹ̀ ti o ti agbedemeji ẹsẹ̀ rẹ̀ jade, ati si awọn ọmọ rẹ̀ ti yio bi; nitoripe on o jẹ wọn ni ìkọkọ nitori ainí ohunkohun: ninu ìdótì ati ihámọ na, ti ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ.
58 Bi iwọ kò ba fẹ́ kiyesi ati ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi ti a kọ sinu iwé yi, lati ma bẹrù orukọ yi ti o lí ogo ti o si lí ẹ̀ru OLUWA ỌLỌRUN RẸ;
59 Njẹ OLUWA yio sọ iyọnu rẹ di iyanu, ati iyọnu irú-ọmọ rẹ, ani iyọnu nla, ati eyiti yio pẹ, ati àrun buburu, ati eyiti yio pẹ.
60 On o si mú gbogbo àrun Egipti pada wá bá ọ, ti iwọ bẹ̀ru; nwọn o si lẹ̀ mọ́ ọ.
61 Gbogbo àrun pẹlu, ati gbogbo iyọnu, ti a kò kọ sinu iwé ofin yi, awọn ni OLUWA yio múwa bá ọ, titi iwọ o fi run.
62 Diẹ li ẹnyin o si kù ni iye, ẹnyin ti ẹ ti dabi irawọ oju-ọrun ni ọ̀pọlọpọ: nitoriti iwọ kò gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́.
63 Yio si ṣe, bi OLUWA ti yọ̀ sori nyin lati ṣe nyin ni ire, ati lati sọ nyin di pupọ̀; bẹ̃ni OLUWA yio si yọ̀ si nyin lori lati run nyin, ati lati pa nyin run; a o si fà nyin tu kuro lori ilẹ na ni ibi ti iwọ nlọ lati gbà a.