1 WỌNYI li ọ̀rọ majẹmu ti OLUWA palaṣẹ fun Mose lati bá awọn ọmọ Israeli dá ni ilẹ Moabu, lẹhin majẹmu ti o ti bá wọn dá ni Horebu.
2 Mose si pè gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ri ohun gbogbo ti OLUWA ṣe li oju nyin ni ilẹ Egipti si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ati si ilẹ rẹ̀ gbogbo.
3 Idanwò nla ti oju rẹ ti ri, iṣẹ-àmi, ati iṣẹ-iyanu nla wọnni:
4 Ṣugbọn OLUWA kò fun nyin li àiya lati mọ̀, ati oju lati ri, ati etí lati gbọ́ titi di oni yi.
5 Emi si ti mu nyin rìn li ogoji ọdún li aginjù: aṣọ nyin kò gbó mọ́ nyin li ara, bàta nyin kò si gbó mọ́ nyin ni ẹsẹ̀.
6 Ẹnyin kò jẹ àkara, bẹ̃li ẹnyin kò mu ọti-waini, tabi ọti lile: ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
7 Nigbati ẹnyin ti dé ihinyi, Sihoni ọba Hesboni, ati Ogu ọba Baṣani, jade ogun si wa, awa si kọlù wọn: