5 Gbogbo ilu wọnyi li a mọ odi giga si pẹlu ibode, ati idabu-ẹ̀kun; laikà ọ̀pọlọpọ ilu alailodi.
6 Awa si run wọn patapata, bi awa ti ṣe si Sihoni ọba Heṣboni, ni rirun awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ patapata, ni ilu na gbogbo.
7 Ṣugbọn gbogbo ohunọ̀sin, ati ikogun ilu wọnni li awa kó ni ikogun fun ara wa.
8 Nigbana li awa gbà li ọwọ́ awọn ọba ọmọ Amori mejeji, ilẹ ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani, lati afonifoji Arnoni lọ dé òke Hermoni;
9 (Awọn ara Sidoni a ma pè Hermoni ni Sirioni, ati awọn ọmọ Amori a si ma pè e ni Seniri;)
10 Gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo Gileadi, ati gbogbo Baṣani, dé Saleka ati Edrei, awọn ilu ilẹ ọba Ogu ni Baṣani.
11 (Ogu ọba Baṣani nikanṣoṣo li o sá kù ninu awọn omirán iyokù; kiyesi i, akete rẹ̀ jẹ́ akete irin; kò ha wà ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni? igbọnwọ mẹsan ni gigùn rẹ̀, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ni igbọnwọ ọkunrin.)