10 Li ọjọ́ ti iwọ duro niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu, nigbati OLUWA wi fun mi pe, Pe awọn enia yi jọ fun mi, emi o si mu wọn gbọ́ ọ̀rọ mi, ki nwọn ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru mi li ọjọ́ gbogbo ti nwọn o wà lori ilẹ, ati ki nwọn ki o le ma kọ́ awọn ọmọ wọn.
11 Ẹnyin si sunmọtosi, ẹ si duro nisalẹ òke nì; òke na si njòna dé agbedemeji ọrun, pẹlu òkunkun, ati awọsanma, ati òkunkun biribiri.
12 OLUWA si sọ̀rọ si nyin lati ãrin iná na wá: ẹnyin gbọ́ ohùn ọ̀rọ na, ṣugbọn ẹ kò ri apẹrẹ kan; kìki ohùn li ẹnyin gbọ́.
13 O si sọ majẹmu rẹ̀ fun nyin, ti o palaṣẹ fun nyin lati ṣe, ani ofin mẹwa nì; o si kọ wọn sara walã okuta meji.
14 OLUWA si paṣẹ fun mi ni ìgba na lati kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a.
15 Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesara nyin gidigidi, nitoripe ẹnyin kò ri apẹrẹ kan li ọjọ́ ti OLUWA bá nyin sọ̀rọ ni Horebu lati ãrin iná wá:
16 Ki ẹnyin ki o má ba bà ara nyin jẹ́, ki ẹ má si lọ ṣe ere gbigbẹ, apẹrẹ ohunkohun, aworán akọ tabi abo.