23 Ẹ ma ṣọra nyin, ki ẹnyin má ba gbagbé majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti o ti bá nyin dá, ki ẹnyin má ba lọ ṣe ere finfin fun ara nyin, tabi aworán ohunkohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti kọ̀ fun ọ.
24 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ ajonirun iná ni, Ọlọrun owú.
25 Nigbati iwọ ba bi ọmọ, ati ọmọ ọmọ, ti ẹ ba si pẹ ni ilẹ na, ti ẹ si bà ara nyin jẹ́, ti ẹ si ṣe ere finfin, tabi aworán ohunkohun, ti ẹ si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA Ọlọrun rẹ lati mu u binu:
26 Mo pè ọrun ati aiye jẹri si nyin li oni, pe lọ́gan li ẹnyin o run kuro patapata ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a; ẹnyin ki yio lò ọjọ́ nyin pẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin o si run patapata.
27 OLUWA yio si tú nyin ká ninu awọn orilẹ-ède, diẹ ni ẹnyin o si kù ni iye ninu awọn orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio darí nyin si.
28 Nibẹ̀ li ẹnyin o si ma sìn oriṣa, iṣẹ ọwọ́ enia, igi ati okuta, ti kò riran, ti kò si gbọran, ti kò jẹun, ti kò si gbõrun.
29 Ṣugbọn bi iwọ ba wá OLUWA Ọlọrun rẹ lati ibẹ̀ lọ, iwọ o ri i, bi iwọ ba fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ wá a.