15 OLUWA yio si gbà àrun gbogbo kuro lọdọ rẹ, ki yio si fi ọkan ninu àrun buburu Egipti, ti iwọ mọ̀, si ọ lara, ṣugbọn on o fi wọn lé ara gbogbo awọn ti o korira rẹ.
16 Iwọ o si run gbogbo awọn enia ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi fun ọ; oju rẹ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn awọn oriṣa wọn; nitoripe idẹkùn li eyinì yio jẹ́ fun ọ.
17 Bi iwọ ba wi li ọkàn rẹ pe, Awọn orilẹ-ède wọnyi pọ̀ jù mi lọ; bawo li emi o ṣe le lé wọn jade?
18 Ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru wọn: ṣugbọn ki iwọ ki o ranti daradara ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Farao, ati si gbogbo Egipti;
19 Idanwò nla ti oju rẹ ri, ati àmi, ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi mú ọ jade: bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio ṣe si gbogbo awọn enia na ẹ̀ru ẹniti iwọ mbà.
20 Pẹlupẹlu OLUWA Ọlọrun rẹ yio rán agbọ́n sinu wọn, titi awọn ti o kù, ti nwọn si fi ara wọn pamọ́ fun ọ yio fi run.
21 Ki iwọ ki o máṣe fòya wọn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lãrin rẹ, Ọlọrun ti o tobi ti o si lẹrù.