13 OLUWA sọ fun mi pẹlu pe, Emi ti ri enia yi, si kiyesi i, enia ọlọrùn lile ni:
14 Yàgo fun mi, ki emi ki o pa wọn run, ki emi si pa orukọ wọn rẹ́ kuro labẹ ọrun: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède ti o lagbara ti o si pọ̀ jù wọn lọ.
15 Emi si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke nì wá, òke na si njóna: walã meji ti majẹmu nì si wà li ọwọ́ mi mejeji.
16 Mo si wò, si kiyesi i, ẹnyin ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin si ti yá ẹgbọrọ-malu didà fun ara nyin: ẹnyin ti yipada kánkán kuro li ọ̀na ti OLUWA ti palaṣẹ fun nyin.
17 Emi si mú walã meji nì, mo si sọ wọn silẹ kuro li ọwọ́ mi mejeji, mo si fọ́ wọn niwaju nyin.
18 Emi si wolẹ niwaju OLUWA bi ti iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru; emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kò mu omi; nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin ti ẹnyin ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju OLUWA, lati mu u binu.
19 Nitoriti emi bẹ̀ru ibinu ati irunu OLUWA si nyin lati pa nyin run. OLUWA si gbọ́ ti emi nigbana pẹlu.