5 Ki iṣe nitori ododo rẹ, tabi nitori pipé ọkàn rẹ, ni iwọ fi nlọ lati gbà ilẹ wọn: ṣugbọn nitori ìwabuburu awọn orilẹ-ède wọnyi li OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn kuro niwaju rẹ, ati ki o le mu ọ̀rọ na ṣẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu.
6 Nitorina ki o yé ọ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ kò fi ilẹ rere yi fun ọ lati ní i nitori ododo rẹ; nitoripe enia ọlọrùn lile ni iwọ.
7 Ranti, máṣe gbagbé, bi iwọ ti mu OLUWA Ọlọrun rẹ binu li aginjù: lati ọjọ́ na ti iwọ ti jade kuro ni ilẹ Egipti, titi ẹnyin fi dé ihin yi, ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA.
8 Ati ni Horebu ẹnyin mu OLUWA binu, OLUWA si binu si nyin tobẹ̃ ti o fẹ́ pa nyin run.
9 Nigbati mo gòke lọ sori òke lati gbà walã okuta wọnni, ani walã majẹmu nì ti OLUWA bá nyin dá, nigbana mo gbé ogoji ọsán, ati ogoji oru lori òke na, emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃li emi kò mu omi.
10 OLUWA si fi walã okuta meji fun mi, ti a fi ika Ọlọrun kọ; ati lara wọn li a kọ ọ gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ na, ti OLUWA bá nyin sọ li òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì.
11 O si ṣe li opin ogoji ọsán ati ogoji oru, ti OLUWA fi walã okuta meji nì fun mi, ani walã majẹmu nì.