8 Ati ni Horebu ẹnyin mu OLUWA binu, OLUWA si binu si nyin tobẹ̃ ti o fẹ́ pa nyin run.
9 Nigbati mo gòke lọ sori òke lati gbà walã okuta wọnni, ani walã majẹmu nì ti OLUWA bá nyin dá, nigbana mo gbé ogoji ọsán, ati ogoji oru lori òke na, emi kò jẹ onjẹ, bẹ̃li emi kò mu omi.
10 OLUWA si fi walã okuta meji fun mi, ti a fi ika Ọlọrun kọ; ati lara wọn li a kọ ọ gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ na, ti OLUWA bá nyin sọ li òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì.
11 O si ṣe li opin ogoji ọsán ati ogoji oru, ti OLUWA fi walã okuta meji nì fun mi, ani walã majẹmu nì.
12 OLUWA si wi fun mi pe, Dide, sọkalẹ kánkán lati ihin lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú lati ilẹ Egipti jade wá, ti bà ara wọn jẹ́; nwọn yipada kánkán kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun wọn; nwọn ti yá ere didà fun ara wọn.
13 OLUWA sọ fun mi pẹlu pe, Emi ti ri enia yi, si kiyesi i, enia ọlọrùn lile ni:
14 Yàgo fun mi, ki emi ki o pa wọn run, ki emi si pa orukọ wọn rẹ́ kuro labẹ ọrun: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède ti o lagbara ti o si pọ̀ jù wọn lọ.