2 Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah;
3 Issakari, Sebuluni, ati Benjamini;
4 Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri.
5 Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti.
6 Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na.
7 Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀si i gidigidi, nwọn si rẹ̀, nwọn si di alagbara nla jọjọ; ilẹ na si kún fun wọn.
8 Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu.