Eks 36 YCE

1 BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ.

2 Mose si pè Besaleli ati Oholiabu, ati gbogbo ọkunrin ọlọgbọ́n inu, ninu ọkàn ẹniti OLUWA fi ọgbọ́n si, ani gbogbo ẹniti inu wọn ru soke lati wá si ibi iṣẹ na lati ṣe e:

3 Nwọn si gbà gbogbo ọrẹ na lọwọ Mose, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, lati fi ṣe e. Sibẹ̀ nwọn si nmú ọrẹ ọfẹ fun u wá li orowurọ̀.

4 Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọgbọ́n, ti o ṣe gbogbo isẹ ibi mimọ́ na, lọ olukuluku kuro ni ibi iṣẹ rẹ̀ ti nwọn ṣe;

5 Nwọn si sọ fun Mose pe, Awọn enia múwa pupọ̀ju fun iṣẹ ìsin na, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe.

6 Mose si paṣẹ, nwọn si ṣe ki nwọn ki o kede yi gbogbo ibudó na ká, wipe, Máṣe jẹ ki ọkunrin tabi obinrin ki o tun ṣe iṣẹkiṣẹ fun ọrẹ ibi mimọ́ na mọ́. Bẹ̃li a da awọn enia lẹkun ati ma múwa.

7 Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju.

8 Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn.

9 Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna.

10 O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn.

11 O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji.

12 Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji.

13 O si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, o si fi ikọ́ wọnni fi aṣọ-tita kan kọ́ ekeji: bẹ̃li o si di odidi agọ́.

14 O si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ fun agọ́ na lori ibugbé na: aṣọ-tita mọkanla li o ṣe wọn.

15 Ìna aṣọ-tita kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ibò aṣọ-tita kan si jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla jẹ́ ìwọn kanna.

16 O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn.

17 O si pa ãdọta ojóbo si ìha eti ikangun aṣọ-tita na ni ibi isolù, ati ãdọta ojóbo li o si pa si eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù.

18 O si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ lati so agọ́ na lù pọ̀, ki o le ṣe ọkan.

19 O si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori eyi.

20 O si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo.

21 Gigùn apáko kan jẹ́ igbọnwọ mẹwa, ati ibú apáko kan jẹ́ igbọnwọ kan on àbọ.

22 Apáko kan ni ìtẹbọ meji, nwọn jìna si ara wọn li ọgbọgba; bẹ̃li o ṣe sara gbogbo apáko agọ́ na.

23 O si fi apáko ṣe agọ́ na; ogún apáko ni fun ìha ọtún, si ìha gusù:

24 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà li o ṣe nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ rẹ̀ meji, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ rẹ̀ meji.

25 Ati fun ìha keji agọ́ na, ti o wà ni ìha ariwa, o ṣe ogún apáko,

26 Ati ogoji ihò-ìtẹbọ wọn ti fadakà; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.

27 Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn o ṣe apáko mẹfa.

28 Apáko meji li o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha mejeji.

29 A si so wọn lù nisalẹ, a si so wọn lù pọ̀ li ori rẹ̀, si oruka kan: bẹ̃li o ṣe si awọn meji ni igun mejeji.

30 Apáko mẹjọ li o wà, ihò-ìtẹbọ wọn si jẹ́ ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun ti fadakà; ìtẹbọ mejimeji li o wà nisalẹ apáko kọkan.

31 O si ṣe ọpá igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na,

32 Ati ọpá marun fun apáko ìha keji agọ́ na, ati ọpá marun fun apáko agọ́ na fun ìha ìwọ-õrùn.

33 O si ṣe ọpá ãrin o yọ jade lara apáko wọnni, lati opin ekini dé ekeji.

34 O si fi wurà bò apáko wọnni, o si fi wurà ṣe oruka wọn, lati ṣe ipò fun ọpá wọnni, o si fi wurà bò ọpá wọnni.

35 O si fi aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ṣe aṣọ-ikele: iṣẹ ọlọnà li o fi ṣe e ti on ti awọn kerubu.

36 O si ṣe opó igi ṣittimu mẹrin si i, o si fi wurà bò wọn: kọkọrọ wọn ti wurà ni, o si dà ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrin fun wọn.

37 O si ṣe aṣọ-isorọ̀ kan fun ẹnu-ọ̀na Agọ́ na, aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti iṣẹ abẹ́rẹ;

38 Ati opó rẹ̀ mararun ti on ti kọkọrọ wọn: o si fi wurà bò ọnà ori wọn, ati ọjá wọn: ṣugbọn idẹ ni ihò-ìtẹbọ wọn mararun.