Eks 10 YCE

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ: nitoriti mo mu àiya rẹ̀ le, ati àiya awọn iranṣẹ rẹ̀, ki emi ki o le fi iṣẹ-àmi mi wọnyi hàn niwaju rẹ̀:

2 Ati ki iwọ ki o le wi li eti ọmọ rẹ, ati ti ọmọ ọmọ rẹ, ohun ti mo ṣe ni Egipti, ati iṣẹ-àmi mi ti mo ṣe ninu wọn; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA.

3 Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si wi fun u pe, Bayi li OLUWA Ọlọrun Heberu wi, Iwọ o ti kọ̀ pẹ tó lati rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju mi? jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.

4 Ṣugbọn bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, li ọla li emi o mú eṣú wá si ẹkùn rẹ:

5 Nwọn o si bò oju ilẹ ti ẹnikan ki yio fi le ri ilẹ: nwọn o si jẹ ajẹkù eyiti o bọ́, ti o kù fun nyin lọwọ yinyin, yio si jẹ igi nyin gbogbo ti o nruwe ninu oko.

6 Nwọn o si kún ile rẹ, ati ile awọn iranṣẹ rẹ gbogbo, ati ile awọn ara Egipti gbogbo; ti awọn baba rẹ, ati awọn baba baba rẹ kò ri ri, lati ìgba ọjọ́ ti nwọn ti wà lori ilẹ titi o fi di oni-oloni. O si yipada, o jade kuro lọdọ Farao.

7 Awọn iranṣẹ Farao si wi fun u pe, ọkunrin yi yio ti ṣe ikẹkùn si wa pẹ to? jẹ ki awọn ọkunrin na ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn OLUWA Ọlọrun wọn: iwọ kò ti imọ̀ pe Egipti run tán?

8 A si tun mú Mose ati Aaroni wá sọdọ Farao: o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ sìn OLUWA Ọlọrun nyin; ṣugbọn awọn tani yio ha lọ?

9 Mose si wipe, Awa o lọ ati ewe ati àgba, ati awọn ọmọkunrin wa ati awọn ọmọbinrin wa, pẹlu awọn agbo, ati ọwọ́-ẹran wa li awa o lọ; nitori ajọ OLUWA ni fun wa:

10 O si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o pẹlu nyin bẹ̃, bi emi o ti jẹ ki ẹ lọ yi, ati awọn ewe nyin: ẹ wò o; nitori ibi mbẹ niwaju nyin.

11 Bẹ̃kọ: ẹnyin ọkunrin ẹ lọ, ki ẹ si sìn OLUWA; eyinì li ẹnyin sá nfẹ́. Nwọn si lé wọn jade kuro niwaju Farao.

12 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ sori ilẹ Egipti nitori eṣú, ki nwọn ki o le wá sori ilẹ Egipti, ki nwọn ki o si le jẹ gbogbo eweko ilẹ yi, gbogbo eyiti yinyin ti kù silẹ.

13 Mose si nà ọpá rẹ̀ si ori ilẹ Egipti, OLUWA si mu afẹfẹ ìla-õrùn kan fẹ́ si ori ilẹ na, ni gbogbo ọsán na, ati gbogbo oru na; nigbati o di owurọ̀, afẹfẹ ila-õrùn mú awọn eṣú na wá.

14 Awọn eṣú na si goke sori ilẹ Egipti gbogbo, nwọn si bà si ẹkùn Egipti gbogbo; nwọn papọ̀ju, kò si irú eṣú bẹ̃ ṣaju wọn, bẹ̃ni lẹhin wọn irú wọn ki yio si si.

15 Nitoriti nwọn bò oju ilẹ gbogbo, tobẹ̃ ti ilẹ fi ṣú; nwọn si jẹ gbogbo eweko ilẹ na, ati gbogbo eso igi ti yinyin kù silẹ: kò si kù ohun tutù kan lara igi, tabi lara eweko igbẹ́, já gbogbo ilẹ Egipti.

16 Nigbana ni Farao ranṣẹ pè Mose ati Aaroni kánkan; o si wipe, Emi ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ati si nyin.

17 Njẹ nitorina emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ẹ̀ṣẹ mi jì lẹ̃kanṣoṣo yi, ki ẹ si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun nyin, ki o le mú ikú yi kuro lọdọ mi.

18 On si jade kuro niwaju Farao, o si bẹ̀ OLUWA.

19 OLUWA si yi afẹfẹ ìwọ-õrùn lile-lile ti o si fẹ́ awọn eṣú na kuro, o si gbá wọn lọ sinu Okun Pupa; kò si kù eṣú kanṣoṣo ni gbogbo ẹkùn Egipti.

20 Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ.

21 OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si ọrun, ki òkunkun ki o ṣú yiká ilẹ Egipti, ani òkunkun ti a le fọwọbà.

22 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si ọrun; òkunkun biribiri si ṣú ni gbogbo ilẹ Egipti ni ijọ́ mẹta:

23 Nwọn kò ri ara wọn, bẹ̃li ẹnikan kò si dide ni ipò tirẹ̀ ni ijọ́ mẹta: ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Israeli li o ni imọle ni ibugbé wọn.

24 Farao si pè Mose, o si wipe, Ẹ ma lọ, ẹ sìn OLUWA; kìki agbo ati ọwọ́-ẹran nyin ni ki o kù lẹhin; ki awọn ewe nyin ki o bá nyin lọ pẹlu.

25 Mose si wipe, Iwọ kò le ṣaima fun wa li ohun ẹbọ pẹlu ati ẹbọ sisun, ti awa o fi rubọ si OLUWA Ọlọrun wa.

26 Ẹran-ọ̀sin wa yio si bá wa lọ pẹlu; a ki yio fi ibósẹ-ẹran kan silẹ lẹhin; nitori ninu rẹ̀ li awa o mú sìn OLUWA Ọlọrun wa; awa kò si mọ̀ ohun na ti a o fi sìn OLUWA, titi awa o fi dé ibẹ̀.

27 Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, kò si fẹ́ jẹ ki nwọn lọ.

28 Farao si wi fun u pe, Kuro lọdọ mi, ma ṣọ́ ara rẹ, máṣe tun ri oju mi mọ́; nitori ni ijọ́ na ti iwọ ba ri oju mi iwọ o kú.

29 Mose si wipe, Iwọ fọ̀ rere; emi ki yio tun ri oju rẹ mọ́.