Eks 37 YCE

1 BESALELI si fi igi ṣittimu ṣe apoti na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀:

2 O si fi kìki wurà bò o ninu ati lode, o si ṣe igbáti wurà si i yiká.

3 O si dà oruka wurà mẹrin fun u, lati fi si igun mẹrẹrin rẹ̀; oruka meji si ìha kini rẹ̀, ati meji si ìha keji rẹ̀.

4 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá, o si fi wurà bò wọn.

5 O si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, lati ma rù apoti na

6 O si fi kìki wurà ṣe itẹ́-ãnu na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀.

7 O si ṣe kerubu wurà meji; iṣẹ lilù li o ṣe wọn, ni ìku mejeji itẹ́-ãnu na;

8 Kerubu kan ni ìku kini, ati kerubu keji ni ìku keji: lati ara itẹ́-ãnu li o ti ṣe awọn kerubu na ni ìku mejeji rẹ̀.

9 Awọn kerubu na si nà iyẹ́-apa wọn soke, nwọn si fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, nwọn si dojukọ ara wọn; itẹ́-ãnu na ni awọn kerubu kọjusi.

10 O si fi igi ṣittimu ṣe tabili kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀:

11 O si fi kìki wurà bò o, o si ṣe igbáti wurà si i yiká.

12 O si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, o si ṣe igbáti wurà kan fun eti rẹ̀ yiká.

13 O si dà oruka wurà mẹrin fun u, o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà ni ibi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rẹ̀.

14 Labẹ igbáti na ni oruka wọnni wà, àye fun ọpá lati fi rù tabili na.

15 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn, lati ma rù tabili na.

16 O si ṣe ohunèlo wọnni ti o wà lori tabili na, awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, lati ma fi dà ohun mimu, kìki wurà ni.

17 O si fi kìki wurà, ṣe ọpá-fitila: iṣẹ lilù li o ṣe ọpá-fitila na; ọpá rẹ̀, ati ẹka rẹ̀, ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn:

18 Ẹka mẹfa li o jade ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan rẹ̀, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na, ni ìha keji rẹ̀.

19 Ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka kan, irudi kan ati itanna; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka keji, irudi kan ati itanna: bẹ̃ni li ẹka mẹfẹfa ti o jade lara ọpá-fitila na.

20 Ati ninu ọpá-fitila na li a ṣe ago mẹrin bi itanna almondi, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀:

21 Ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, gẹgẹ bi ẹka mẹfẹfa ti o jade lara rẹ̀.

22 Irudi wọn ati ẹka wọn jẹ bakanna: gbogbo rẹ̀ jẹ́ iṣẹ lilù kìki wurà kan.

23 O si ṣe fitila rẹ̀, meje, ati alumagaji rẹ̀, ati awo rẹ̀, kìki wurà ni.

24 Talenti kan kìki wurà li o fi ṣe e, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀.

25 O si fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ turari: gigùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, ibú rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ kan, ìha mẹrin ọgbọgba; giga rẹ̀ si jẹ́ igbọnwọ meji; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀.

26 O si fi kìki wurà bò o, ati òke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀: o si ṣe igbáti wurà si i yiká.

27 O si ṣe oruka wurà meji si i nisalẹ̀ igbáti rẹ̀ na, ni ìha igun rẹ̀ meji, ìha mejeji rẹ̀, lati ṣe àye fun ọpá wọnni lati ma fi rù u.

28 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn.

29 O si ṣe oróro mimọ́ itasori nì, ati õrùn didùn kìki turari, gẹgẹ bi iṣẹ alapòlu.