1 NIGBATI awọn enia ri pe, Mose pẹ lati sọkalẹ ti ori òke wá, awọn enia kó ara wọn jọ sọdọ Aaroni, nwọn si wi fun u pe, Dide, dá oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa lọ; bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.
2 Aaroni si wi fun wọn pe, Ẹ kán oruka wurà ti o wà li eti awọn aya nyin, ati ti awọn ọmọkunrin nyin, ati ti awọn ọmọbinrin nyin, ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá.
3 Gbogbo awọn enia si kán oruka wurà ti o wà li eti wọn, nwọn si mú wọn tọ̀ Aaroni wá.
4 O si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si fi ohun-ọnà fifin ṣe e, nigbati o si dà a li aworan ẹgbọrọmalu tán: nwọn si wipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ Egipti wá.
5 Nigbati Aaroni si ri i, o tẹ́ pẹpẹ kan niwaju rẹ̀; Aaroni si kede, o si wipe, Ọla li ajọ fun OLUWA.
6 Nwọn si dide ni kùtukutu ijọ́ keji nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si mú ẹbọ alafia wá; awọn enia si joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire.
7 OLUWA si sọ fun Mose pe, Lọ, sọkalẹ lọ; nitoriti awọn enia rẹ, ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, nwọn ti ṣẹ̀.
8 Nwọn ti yipada kánkan kuro ni ipa-ọ̀na ti mo làsilẹ fun wọn: nwọn ti dá ere ẹgbọrọmalu fun ara wọn, nwọn si ti mbọ ọ, nwọn si ti rubọ si i, nwọn nwipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ̀ Egipti wá.
9 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi ti ri awọn enia yi, si kiyesi i, ọlọrùn lile enia ni:
10 Njẹ nisisiyi jọwọ mi jẹ, ki ibinu mi ki o gbona si wọn, ki emi ki o le pa wọn run: emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla.
11 Mose si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, OLUWA, ẽtiṣe ti ibinu rẹ fi gbona si awọn enia rẹ, ti iwọ fi ipá nla ati ọwọ́ agbara rẹ mú lati ilẹ Egipti jade wá?
12 Nitori kini awọn ara Egipti yio ṣe sọ wipe, Nitori ibi li o ṣe mú wọn jade, lati pa wọn lori oke, ati lati run wọn kuro lori ilẹ? Yipada kuro ninu ibinu rẹ ti o muna, ki o si yi ọkàn pada niti ibi yi si awọn enia rẹ.
13 Ranti Abrahamu, Isaaki, ati Israeli awọn iranṣẹ rẹ, ẹniti iwọ fi ara rẹ bura fun, ti iwọ si wi fun wọn pe, Emi o mu irú-ọmọ nyin bisi i bi irawọ ọrun, ati gbogbo ilẹ na ti mo ti sọ nì, irú-ọmọ nyin li emi o fi fun, nwọn o si jogún rẹ̀ lailai.
14 OLUWA si yi ọkàn pada niti ibi na ti o ti sọ pe on o ṣe si awọn enia rẹ̀.
15 Mose si yipada, o si sọkalẹ lati ori òke na wá, walã ẹrí meji nì si wà li ọwọ́ rẹ̀; walã ti a kọwe si ni ìha mejeji; lara ekini ati ekeji li a kọwe si.
16 Iṣẹ́ Ọlọrun si ni walã wọnni, ikọwe na ni ikọwe Ọlọrun, a fin i sara walã na.
17 Nigbati Joṣua si gbọ́ ariwo awọn enia na, bi nwọn ti nhó, o wi fun Mose pe, Ariwo ogun mbẹ ni ibudó.
18 Mose si wi pe, Ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nhó nitori iṣẹgun, bẹ̃ni ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nkigbe pe a ṣẹgun wọn: ohùn awọn ti nkọrin ni mo gbọ́ yi.
19 O si ṣe, bi o ti sunmọ ibudó, o si ri ẹgbọrọmalu na, ati agbo ijó: ibinu Mose si ru gidigidi, o si sọ walã wọnni silẹ kuro li ọwọ́ rẹ̀, o si fọ́ wọn nisalẹ òke na.
20 O si mú ẹgbọrọ-malu na ti nwọn ṣe, o si sun u ni iná, o si lọ̀ ọ di ẹ̀tu, o si kù u soju omi, o si mu awọn ọmọ Israeli mu u.
21 Mose si wi fun Aaroni pe, Kili awọn enia wọnyi fi ṣe ọ, ti iwọ fi mú ẹ̀ṣẹ̀ nla wá sori wọn?
22 Aaroni si wipe, Máṣe jẹ ki ibinu oluwa mi ki o gbona: iwọ mọ̀ awọn enia yi pe, nwọn buru.
23 Awọn li o sa wi fun mi pe, Ṣe oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa: bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.
24 Emi si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba ni wurà, ki nwọn ki o kán a kuro; bẹ̃ni nwọn fi fun mi: nigbana li emi fi i sinu iná, ẹgbọrọmalu yi si ti jade wá.
25 Nigbati Mose ri i pe awọn enia na kò ṣe ikoso; nitoriti Aaroni sọ wọn di alailakoso lãrin awọn ti o dide si wọn.
26 Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀.
27 O si wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli, wipe, Ki olukuluku ọkunrin ki o kọ idà rẹ̀ si ẹgbẹ́ rẹ̀, ki ẹ si ma wọle, ki ẹ si ma jade lati ẹnubode dé ẹnubode já gbogbo ibudó, olukuluku ki o si pa arakunrin rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa ẹgbẹ rẹ̀, ati olukuluku ki o si pa aladugbo rẹ̀.
28 Awọn ọmọ Lefi si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose: awọn ti o ṣubu ninu awọn enia li ọjọ́ na to ìwọn ẹgbẹdogun enia.
29 Mose sa ti wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ li oni fun OLUWA, ani olukuluku ọkunrin lara ọmọ rẹ̀, ati lara arakunrin rẹ̀; ki o le fi ibukún si nyin lori li oni.
30 O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Mose wi fun awọn enia pe, Ẹnyin dá ẹ̀ṣẹ nla: njẹ nisisiyi, emi o gòke tọ̀ OLUWA, bọya emi o ṣètutu fun ẹ̀ṣẹ nyin.
31 Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wipe, Yẽ, awọn enia wọnyi ti dá ẹ̀ṣẹ nla, nwọn si dá oriṣa wurà fun ara wọn.
32 Nisisiyi, bi iwọ o ba dari ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn; bi bẹ̃ si kọ, emi bẹ̀ ọ, pa mi rẹ́ kuro ninu iwé rẹ ti iwọ ti kọ.
33 OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹnikẹni ti o ṣẹ̀ mi, on li emi o parẹ́ kuro ninu iwé mi.
34 Njẹ nisisiyi lọ, ma mú awọn enia na lọ si ibiti mo ti sọ fun ọ: kiyesi i, angeli mi yio ṣaju rẹ: ṣugbọn li ọjọ́ ti emi o ṣe ìbẹwo, emi o bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò lara wọn.
35 OLUWA si yọ awọn enia na lẹnu, nitoriti nwọn ṣe ẹgbọrọ-malu, ti Aaroni ṣe.