1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Tọ̀ Farao lọ, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.
2 Bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki nwọn ki o lọ, kiyesi i, emi o fi ọpọlọ kọlù gbogbo ẹkùn rẹ:
3 Odò yio si bi ọpọlọ jade li ọ̀pọlọpọ, nwọn o si goke, nwọn o si wá sinu ile rẹ, ati sinu ibùsun rẹ, ati sori akete rẹ, ati sinu ile awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu ãro rẹ, ati sinu ọpọ́n ìpo-iyẹfun rẹ:
4 Awọn ọpọlọ na yio si gùn ọ lara, ati lara awọn enia rẹ, ati lara gbogbo awọn iranṣẹ rẹ.
5 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Nà ọwọ́ rẹ pẹlu ọpá rẹ sori odò wọnni, sori omi ṣiṣàn, ati sori ikojọpọ̀ omi, ki o si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.
6 Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ sori omi Egipti; awọn ọpọlọ si goke wá, nwọn si bò ilẹ Egipti.
7 Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃, nwọn si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.
8 Nigbana ni Farao pè Mose ati Aaroni, o si wipe, Ẹ bẹ̀ OLUWA, ki o le mú awọn ọpọlọ kuro lọdọ mi, ati kuro lọdọ awọn enia mi; emi o si jẹ ki awọn enia na ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣẹbọ si OLUWA.
9 Mose si wi fun Farao pe, Paṣẹ fun mi: nigbawo li emi o bẹ̀bẹ fun ọ, ati fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun awọn enia rẹ, lati run awọn ọpọlọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ki nwọn ki o kù ni kìki odò nikan?
10 On si wipe, Li ọla. O si wipe, Ki o ri bi ọ̀rọ rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe, kò sí ẹniti o dabi OLUWA Ọlọrun wa.
11 Awọn ọpọlọ yio si lọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ; ni kìki odò ni nwọn o kù si.
12 Mose ati Aaroni si jade kuro lọdọ Farao: Mose si kigbe si OLUWA nitori ọpọlọ ti o ti múwa si ara Farao.
13 OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; awọn ọpọlọ na si kú kuro ninu ile, ninu agbalá, ati kuro ninu oko.
14 Nwọn si kó wọn jọ li òkiti-òkiti: ilẹ na si nrùn.
15 Ṣugbọn nigbati Farao ri pe isimi wà, o mu àiya rẹ̀ le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
16 OLUWA si wi fun Mose pe, Sọ fun Aaroni pe, Nà ọpá rẹ, ki o si lù ekuru ilẹ, ki o le di iná já gbogbo ilẹ Egipti.
17 Nwọn si ṣe bẹ̃; Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ pẹlu ọpá rẹ̀, o si lù erupẹ ilẹ, iná si wà lara enia, ati lara ẹran; gbogbo ekuru ilẹ li o di iná já gbogbo ilẹ Egipti.
18 Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃ lati mú iná jade wá, ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: bẹ̃ni iná si wà lara enia, ati lara ẹran.
19 Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
20 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.
21 Bi iwọ kò ba si jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, kiyesi i, emi o rán ọwọ́ eṣinṣin si ọ, ati sara iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu awọn ile rẹ: gbogbo ile awọn ara Egipti ni yio si kún fun ọwọ́ eṣinṣin, ati ilẹ ti nwọn gbé wà pẹlu.
22 Li ọjọ́ na li emi o yà ilẹ Goṣeni sọ̀tọ, ninu eyiti awọn enia mi tẹ̀dó si, ti eṣinṣin ki yio sí nibẹ̀; nitori ki iwọ ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA lãrin ilẹ aiye.
23 Emi o si pàla si agbedemeji awọn enia mi ati awọn enia rẹ: li ọla ni iṣẹ-amì yi yio si wà.
24 OLUWA si ṣe bẹ̃; ọwọ́ eṣinṣin ọ̀pọlọpọ si dé sinu ile Farao, ati sinu ile awọn iranṣẹ rẹ̀: ati ni gbogbo ilẹ Egipti, ilẹ na bàjẹ́ nitori ọwọ́ eṣinṣin wọnni.
25 Farao si ranṣẹ pè Mose ati Aaroni o si wipe; Ẹ ma lọ ṣẹbọ si Ọlọrun nyin ni ilẹ yi.
26 Mose si wipe, Kò tọ́ lati ṣe bẹ̃; nitori awa o fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ si OLUWA Ọlọrun wa: wò o, awa le fi ohun irira awọn ara Egipti rubọ li oju wọn, nwọn ki yio ha sọ wa li okuta?
27 Awa o lọ ni ìrin ijọ́ mẹta sinu ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa, bi on o ti paṣẹ fun wa.
28 Farao si wipe, Emi o jẹ ki ẹnyin lọ, ki ẹ le rubọ si OLUWA Ọlọrun nyin ni ijù; kìki ki ẹnyin ki o máṣe lọ jìna jù: ẹ bẹ̀bẹ fun mi.
29 Mose si wipe, Kiyesi i, emi njade lọ kuro lọdọ rẹ, emi o si bẹ̀ OLUWA ki ọwọ́ eṣinṣin wọnyi ki o le ṣi kuro lọdọ Farao, kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀, li ọla: kìki ki Farao ki o máṣe ẹ̀tan mọ́ li aijẹ ki awọn enia na ki o lọ rubọ si OLUWA.
30 Mose si jade kuro lọdọ Farao, o si bẹ̀ OLUWA.
31 OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; o si ṣi ọwọ́ eṣinṣin na kuro lọdọ Farao, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ̀, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ̀; ọkan kò kù.
32 Farao si mu àiya rẹ̀ le nigbayi pẹlu, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ.