Eks 15 YCE

1 NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun.

2 OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di ìgbala mi: eyi li Ọlọrun mi, emi o si fi ìyin fun u; Ọlọrun baba mi, emi o gbé e leke.

3 Ologun li OLUWA; OLUWA li orukọ rẹ̀.

4 Kẹkẹ́ Farao ati ogun rẹ̀ li o mu wọ̀ inu okun: awọn ãyo olori ogun rẹ̀ li o si rì ninu Okun Pupa.

5 Ibú bò wọn mọlẹ: nwọn rì si isalẹ bi okuta.

6 OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ li ogo ninu agbara: OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ fọ́ ọtá tútu.

7 Ati ni ọ̀pọlọpọ ọlá rẹ ni iwọ bì awọn ti o dide si ọ ṣubu; iwọ rán ibinu rẹ, ti o run wọn bi akemọlẹ idi koriko.

8 Ati nipa ẽmi imu rẹ, li omi si fi wọjọ pọ̀, ìṣan omi dide duro gangan bi ogiri; ibú si dìlu lãrin okun.

9 Ọtá wipe, Emi o lepa, emi o bá wọn, emi o pín ikogun: a o tẹ́ ifẹkufẹ mi lọrùn lara wọn; emi o fà dà mi yọ, ọwọ́ mi ni yio pa wọn run.

10 Iwọ si mu afẹfẹ rẹ fẹ́, okun bò wọn mọlẹ: nwọn rì bi ojé ninu omi nla.

11 Tali o dabi iwọ, OLUWA, ninu awọn alagbara? tali o dabi iwọ, ologo ni mimọ́, ẹlẹru ni iyìn, ti nṣe ohun iyanu?

12 Iwọ nà ọwọ́ ọtún rẹ, ilẹ gbe wọn mì.

13 Ninu ãnu rẹ ni iwọ fi ṣe amọ̀na awọn enia na ti iwọ ti rapada: iwọ si nfi agbara rẹ tọ́ wọn lọ si ibujoko mimọ́ rẹ.

14 Awọn enia gbọ́, nwọn warìri; ikãnu si mú awọn olugbe Palestina.

15 Nigbana li ẹnu yà awọn balẹ Edomu; iwarìri si mú awọn alagbara Moabu: gbogbo awọn olugbe Kenaani yọ́ dànu.

16 Ibẹru-bojo mú wọn; nipa titobi apa rẹ nwọn duro jẹ bi okuta; titi awọn enia rẹ fi rekọja, OLUWA, titi awọn enia rẹ ti iwọ ti rà fi rekọja.

17 Iwọ o mú wọn wọle, iwọ o si gbìn wọn sinu oke ilẹ-iní rẹ, OLUWA, ni ibi ti iwọ ti ṣe fun ara rẹ, lati mã gbé, OLUWA; ni ibi mimọ́ na, ti ọwọ́ rẹ ti gbekalẹ.

18 OLUWA yio jọba lai ati lailai.

19 Nitori ẹṣin Farao wọ̀ inu okun lọ, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, OLUWA si tun mú omi okun pada si wọn lori; ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni ilẹ gbigbẹ lãrin okun.

20 Ati Miriamu wolĩ obinrin, arabinrin Aaroni, o mú ìlu li ọwọ́ rẹ̀: gbogbo awọn obinrin si jade tẹle e ti awọn ti ìlu ati ijó.

21 Miriamu si da wọn li ohùn pe, Ẹ kọrin si OLUWA nitoriti o pọ̀ li ogo; ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun.

22 Bẹ̃ni Mose mú Israeli jade lati Okun Pupa wá, nwọn si jade lọ si ijù Ṣuri; nwọn si lọ ni ìrin ijọ́ mẹta ni ijù na, nwọn kò si ri omi.

23 Nigbati nwọn dé Mara, nwọn ko le mu ninu omi Mara, nitoriti o korò; nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Mara.

24 Awọn enia na si nkùn si Mose wipe, Kili awa o mu?

25 O si kepè OLUWA; OLUWA si fi igi kan hàn a, nigbati o si sọ ọ sinu omi na, omi si di didùn. Nibẹ̀ li o si gbé ṣe ofin ati ìlana fun wọn, nibẹ̀ li o si gbé dán wọn wò;

26 O si wipe, Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o ba si ṣe eyiti o tọ́ li oju rẹ̀, ti iwọ o ba si fetisi ofin rẹ̀, ti iwọ o ba si pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́, emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo múwa sara awọn ara Egipti si ọ lara: nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá.

27 Nwọn si dé Elimu, nibiti kanga omi mejila gbé wà, ati ãdọrin ọpẹ: nwọn si dó si ìha omi wọnni nibẹ̀.