Eks 40 YCE

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Li ọjọ́ kini oṣù kini ni ki iwọ ki o gbé ibugbé agọ́ na ró.

3 Iwọ o si fi apoti ẹrí nì sinu rẹ̀, iwọ o si ta aṣọ-ikele ni bò apoti na.

4 Iwọ o si gbé tabili wọle, ki o si tò ohun wọnni ti o ni itò si ori rẹ̀; iwọ o si mú ọpá-fitila wọle, iwọ o si tò fitila rẹ̀ wọnni lori rẹ̀.

5 Iwọ o si fi pẹpẹ wurà ti turari nì si iwaju apoti ẹrí, iwọ o si fi aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na sara agọ́ na.

6 Iwọ o si fi pẹpẹ ẹbọsisun nì si iwaju ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ.

7 Iwọ o si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀.

8 Iwọ o si fà agbalá na yiká, iwọ o si ta aṣọ-isorọ̀ si ẹnu-ọ̀na agbalá na.

9 Iwọ o si mù oróro itasori nì, iwọ o si ta a sara agọ́ na, ati sara ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀: yio si jẹ́ mimọ́.

10 Iwọ o si ta oróro sara pẹpẹ ẹbọsisun, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, iwọ o si yà pẹpẹ na simimọ́: yio si ma jẹ́ pẹpẹ ti o mọ́ julọ.

11 Iwọ o si ta oróro sara agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́.

12 Iwọ o si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn.

13 Iwọ o si fi aṣọ mimọ́ wọnni wọ̀ Aaroni; iwọ o si ta oróro si i li ori, iwọ o si yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

14 Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá, iwọ o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn:

15 Iwọ o si ta oróro si wọn li ori, bi iwọ ti ta si baba wọn li ori, ki nwọn ko le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi: nitoriti itasori wọn yio jẹ́ iṣẹ-alufa lailai nitõtọ, lati irandiran wọn.

16 Bẹ̃ni Mose ṣe: gẹgẹ bi eyiti OLUWA palaṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe.

17 O si ṣe li oṣù kini li ọdún keji ni ijọ́ kini oṣù na, ni a gbé agọ́ na ró.

18 Mose si gbé agọ́ na ró, o si de ihò-ìtẹbọ rẹ̀, o si tò apáko rẹ̀, o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ, o si gbé ọwọ̀n rẹ̀ ró.

19 O si nà aṣọ agọ́ na sori agọ́, o si fi ibori agọ́ na bò o li ori; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

20 O si mú, o si fi ẹrí nì sinu apoti na, o si fi ọpá wọnni sara apoti na, o si fi itẹ́-ãnu nì si oke lori apoti na:

21 O si gbé apoti na wá sinu agọ́, o si ta aṣọ-ikele, o si ta a bò apoti ẹrí; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

22 O si fi tabili nì sinu agọ́ ajọ, ni ìha ariwa agọ́ na, lẹhin ode aṣọ-ikele nì.

23 O si tò àkara na lẹ̀sẹsẹ daradara lori rẹ̀ niwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

24 O si fi ọpá-fitila nì sinu agọ́ ajọ, ki o kọjusi tabili nì ni ìha gusù agọ na.

25 O si tàn fitila wọnni siwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

26 O si fi pẹpẹ wurà nì sinu agọ́ ajọ niwaju aṣọ-ikele nì:

27 O si fi turari didùn joná lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

28 O si ta aṣọ-isorọ̀ nì si ẹnu-ọ̀na agọ́ na.

29 O si fi pẹpẹ ẹbọsisun si ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ, o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

30 O si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, o si pọn omi si i, lati ma fi wẹ̀.

31 Ati Mose ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wẹ̀ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn ninu rẹ̀.

32 Nigbati nwọn ba lọ sinu agọ́ ajọ, ati nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ na, nwọn a wẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

33 O si fà agbalá na yi agọ́ ati pẹpẹ na ká, o si ta aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na. Bẹ̃ni Mose pari iṣẹ na.

34 Nigbana li awọsanma bò agọ́ ajọ, ogo OLUWA si kún inu agọ́ na.

35 Mose kò si le wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nitoriti awọsanma wà lori rẹ̀, ogo OLUWA si kun inu agọ́ na.

36 Nigbati a si fà awọsanma na soke, kuro lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a ma dide rìn lọ ni ìrin wọn gbogbo:

37 Ṣugbọn bi a kò fà awọsanma na soke, njẹ nwọn kò ni idide rìn titi ọjọ-kọjọ́ ti o ba fà soke.

38 Nitoriti awọsanma OLUWA wà lori agọ́ na li ọsán, iná si wà ninu awọsanma na li oru, li oju gbogbo ile Israeli, ni gbogbo ìrin wọn.