1 OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi fi ọ ṣe ọlọrun fun Farao: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma ṣe wolĩ rẹ.
2 Iwọ o sọ gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma sọ fun Farao pe, ki o rán awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ rẹ̀.
3 Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti.
4 Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti.
5 Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba nà ọwọ́ mi lé Egipti, ti mo si mú awọn ọmọ Israeli jade kuro lãrin wọn.
6 Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃; bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn; bẹ̃ni nwọn ṣe.
7 Mose jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún, Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọrin ọdún o le mẹta, nigbati nwọn sọ̀rọ fun Farao.
8 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
9 Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò.
10 Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò.
11 Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ.
12 Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì.
13 Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
14 OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
15 Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ.
16 Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́.
17 Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ.
18 Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na.
19 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta.
20 Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ.
21 Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti,
22 Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.
23 Farao si pada o lọ si ile rẹ̀, kò si fi ọkàn rẹ̀ si eyi pẹlu.
24 Gbogbo awọn ara Egipti si wàlẹ yi odò na ká fun omi mimu; nitoriti nwọn kò le mu ninu omi na.
25 Ọjọ́ meje si pé, lẹhin igbati OLUWA lù odò na.