1 ỌKUNRIN kan ara ile Lefi si lọ, o si fẹ́ ọmọbinrin Lefi kan.
2 Obinrin na si yún, o si bi ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, o ṣe ọmọ didara, o pa a mọ́ li oṣù mẹta.
3 Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na.
4 Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na.
5 Ọmọbinrin Farao si sọkalẹ wá lati wẹ̀ li odò; awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ si nrìn lọ li ẹba odò na; nigbati o si ri apoti na lãrin koriko odò, o rán ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ kan lati lọ gbé e wá.
6 Nigbati o si ṣi i, o ri ọmọ na; si kiyesi i ọmọde na nsọkun. Inu rẹ̀ si yọ́ si i, o si wipe, Ọkan ninu awọn ọmọ Heberu li eyi.
7 Nigbana li arabinrin rẹ̀ wi fun ọmọbinrin Farao pe, Emi ka lọ ipè alagbatọ kan fun ọ wá ninu awọn obinrin Heberu, ki o tọ́ ọmọ na fun ọ?
8 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Lọ. Ọmọbinrin na si lọ, o si pè iya ọmọ na wá.
9 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Gbé ọmọ yi lọ ki o si tọ́ ọ fun mi, emi o si san owo iṣẹ rẹ fun ọ. Obinrin na si gbé ọmọ na lọ, o si tọ́ ọ.
10 Ọmọ na si dàgba, o si mú u tọ̀ ọmọbinrin Farao wá, on si di ọmọ rẹ̀. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Mose, o si wipe, Nitoriti mo fà a jade ninu omi.
11 O si ṣe li ọjọ́ wọnni, ti Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò iṣẹ wọn: o si ri ara Egipti kan o nlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀.
12 O si wò ihin, o wò ọhún, nigbati o si ri pe, kò si ẹnikan, o lù ara Egipti na pa, o si bò o ninu yanrin.
13 Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ?
14 On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀.
15 Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan.
16 Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn.
17 Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn.
18 Nigbati nwọn si padà dé lati ọdọ Reueli baba wọn, o ni Ẽtiri ti ẹnyin fi tète dé bẹ̃ loni?
19 Nwọn si wipe, Ara Egipti kan li o gbà wa lọwọ awọn oluṣọ-agutan, o si pọn omi to fun wa pẹlu, o si fi fun agbo-ẹran.
20 O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe Nibo li o gbé wà? ẽṣe ti ẹnyin fi ọkunrin na silẹ? ẹ pè e ki o le wá ijẹun.
21 O si dùn mọ́ Mose lati ma bá ọkunrin na gbé: on si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose.
22 On si bi ọmọkunrin kan fun u, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gerṣomu: nitoriti o wipe, Emi ti nṣe atipo ni ilẹ ajeji.
23 O si ṣe lẹhin ọjọ́ pupọ̀, ti ọba Egipti kú: awọn ọmọ Israeli si ngbin nitori ìsin na, nwọn si ke, igbe wọn si goke tọ̀ Ọlọrun lọ nitori ìsin wọn.
24 Ọlọrun si gbọ́ irora wọn, Ọlọrun si ranti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, pẹlu Isaaki, ati pẹlu Jakobu.
25 Ọlọrun si bojuwò awọn ọmọ Israeli, Ọlọrun si mọ̀ ọ fun wọn.