Eks 11 YCE

Mose Kéde Ikú Àwọn Àkọ́bí

1 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o tun mú iyọnu kan wá sara Farao, ati sara Egipti; lẹhin eyinì ni on o jọwọ nyin lọwọ lọ lati ihin: nigbati on o jẹ ki ẹ lọ, àtitán ni yio tì nyin jade nihin.

2 Wi nisisiyi li eti awọn enia wọnyi, ki olukuluku ọkunrin ki o bère lọdọ aladugbo rẹ̀ ati olukuluku obinrin lọdọ aladugbo rẹ̀, ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà.

3 OLUWA si fi ojurere fun awọn enia na li oju awọn ara Egipti. Pẹlupẹlu Mose ọkunrin nì o pọ̀ gidigidi ni ilẹ Egipti, li oju awọn iranṣẹ Farao, ati li oju awọn enia na.

4 Mose si wipe, Bayi li OLUWA wi, Lãrin ọganjọ li emi o jade lọ sãrin Egipti:

5 Gbogbo awọn akọ́bi ti o wà ni ilẹ Egipti ni yio si kú, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀, titi yio si fi dé akọ́bi iranṣẹbinrin ti o wà lẹhin ọlọ; ati gbogbo akọ́bi ẹran.

6 Ẹkún nla yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, eyiti irú rẹ̀ kò si ri, ti ki yio si si irú rẹ̀ mọ́.

7 Ṣugbọn si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli li ajá ki yio yọ ahọn rẹ̀, si enia tabi si ẹran: ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi OLUWA ti fi ìyatọ sãrin awọn ara Egipti ati Israeli.

8 Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ni yio si sọkalẹ tọ̀ mi wá, ti nwọn o si fori wọn balẹ fun mi pe, Iwọ jade lọ ati gbogbo awọn enia ẹhin rẹ: lẹhin ìgba na li emi o to jade. O si jade kuro niwaju Farao ni ibinu nla.

9 OLUWA si wi fun Mose pe, Farao ki yio gbọ́ tirẹ; ki a le sọ iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti.

10 Mose ati Aaroni si ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu wọnyi niwaju Farao: OLUWA si mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si fẹ́ jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o jade lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.