Eks 39 YCE

1 NWỌN si fi ninu aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, dá aṣọ ìsin, lati ma fi sìn ni ibi mimọ́, nwọn si dá aṣọ mimọ́ ti iṣe fun Aaroni; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

2 O si ṣe ẹ̀wu-efodi na ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

3 Nwọn si lù wurà nì di ewé fẹlẹfẹlẹ, nwọn si là a li okùn wẹ́wẹ, ati lati fi ṣe iṣẹ ọlọnà sinu aṣọ-alaró, ati sinu elesè-àluko, ati sinu ododó, ati sinu ọ̀gbọ didara nì.

4 Nwọn ṣe aṣọ ejika si i, lati so o lù: li eti mejeji li a so o lù.

5 Ati onirũru-ọnà ọjá ti o wà lara rẹ̀, lati fi dì i o jẹ́ ọkanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, aṣọ-alaró, elesè-àluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

6 Nwọn si ṣiṣẹ́ okuta oniki ti a tò sinu oju-ìde wurà, ti a fin bi ifin èdidi-àmi ti a fin orukọ awọn ọmọ Israeli si.

7 O si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi na, li okuta, iranti fun awọn ọmọ Israeli: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

8 O si fi iṣẹ ọlọnà ṣiṣẹ igbàiya na, bi iṣẹ ẹ̀wu-efodi nì; ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododo, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

9 Oniha mẹrin ọgbọgba ni; nwọn ṣe igbàiya na ni iṣẹpo meji: ika kan ni gigùn rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀, o jẹ́ iṣẹpo meji.

10 Nwọn si tò ẹsẹ̀ okuta mẹrin si i: ẹsẹ̀ ekini ni sardiu, ati topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini.

11 Ati ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi.

12 Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu.

13 Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, oniki, ati jasperi: a si tò wọn si oju-ìde wurà ni titò wọn.

14 Okuta wọnni si jasi gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn, bi ifin èdidi-àmi, olukuluku ti on ti orukọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ya mejejila.

15 Nwọn si ṣe ẹ̀wọn iṣẹ-ọnà-lilọ kìki wurà si igbàiya na.

16 Nwọn si ṣe oju-ìde wurà meji, ati oruka wurà meji; nwọn si fi oruka mejeji si eti igbàiya na mejeji.

17 Nwọn si fi ẹ̀wọn wurà iṣẹ-ọnà-lilọ mejeji bọ̀ inu oruka wọnni, ni eti igbàiya na.

18 Ati eti mejeji ti ẹ̀wọn iṣẹ-lilọ mejeji nì ni nwọn fi mọ́ inu oju-ìde mejeji, nwọn si fi wọn sara okùn ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀.

19 Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si eti mejeji igbàiya na, si eti rẹ̀ ti o wà, ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inu.

20 Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si ìha mejeji ẹ̀wu-efodi na nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ki o kọjusi isolù rẹ̀, loke ọjá ẹ̀wu-efodi na.

21 Nwọn si fi oruka rẹ̀ dè igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi pẹlu ọjá-àwọn aṣọ-aláró, ki o le ma wà lori onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ati ki igbàiya ni ki o máṣe tú kuro lara ẹ̀wu-efodi na; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

22 O si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni iṣẹ wiwun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ-aláró.

23 Oju-ọrùn si wà li agbedemeji aṣọ-igunwa na, o dabi oju-ẹ̀wu ogun, pẹlu ọjá yi oju na ká, ki o máṣe ya.

24 Nwọn si ṣe pomegranate aṣọ: alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ si iṣẹti aṣọ-igunwa na.

25 Nwọn si ṣe ṣaworo kìki wurà, nwọn si fi ṣaworo na si alafo pomegranate wọnni si eti iṣẹti aṣọ igunwa na, yiká li alafo pomegranate wọnni;

26 Ṣaworo kan ati pomegranate kan, ṣaworo kan ati pomegranate kan, yi iṣẹti aṣọ-igunwa na ká lati ma fi ṣiṣẹ alufa; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

27 Nwọn si ṣe ẹ̀wu ọ̀gbọ daradara ti iṣẹ híhun fun Aaroni, ati fun awọn ọmo rẹ̀,

28 Ati fila ọṣọ́ ọ̀gbọ daradara, ati fila ọ̀gbọ didara, ati ṣòkoto ọ̀gbọ olokún wiwẹ,

29 Ati ọjá ọ̀gbọ olokùn wiwẹ́, ati ti aṣọ-alaró, ti elesè-àluko, ati ti ododo, oniṣẹ abẹ́rẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

30 Nwọn si ṣe awo adé mimọ́ na ni kìki wurà, nwọn si kọwe si i, ikọwe bi fifin èdidi-àmi, MIMỌ SI OLUWA.

31 Nwọn si dì ọjá àwọn alaró mọ́ ọ, lati fi dì i loke sara fila na; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

32 Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ agọ́ ti agọ́ ajọ na pari: awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA palaṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.

33 Nwọn si mú agọ́ na tọ̀ Mose wá, agọ́ na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ikọ́ rẹ̀, apáko rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ati ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ wọnni;

34 Ati ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati ibori awọ seali, ati ikele aṣọ-tita.

35 Apoti ẹrí nì, ati ọpá rẹ̀ wọnni, ati itẹ́-ãnu nì;

36 Tabili na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati àkara ifihàn;

37 Ọpá-fitila mimọ́, pẹlu fitila rẹ̀ wọnni, fitila ti a tò li ẹsẹ̀-ẹsẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati oróro titanna;

38 Ati pẹpẹ wurà, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na;

39 Pẹpẹ idẹ, ati oju-àro-àwọn idẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, agbada na ati ẹsẹ̀ rẹ̀;

40 Aṣọ-tita agbalá na, ọwọ̀n rẹ̀ ati ihò-ìtẹbọ̀ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na, okùn rẹ̀, ati ekàn rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo ìsin agọ́ na, ani agọ́ ajọ;

41 Aṣọ ìsin lati ma fi sìn ninu ibi mimọ́, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa.

42 Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA fi aṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe gbogbo iṣẹ na.

43 Mose si bojuwò gbogbo iṣẹ na, si kiyesi i, nwọn si ṣe e bi OLUWA ti palaṣẹ, bẹ̃ gẹgẹ ni nwọn ṣe e; Mose si sure fun wọn.