Eks 12 YCE

Àjọ Ìrékọjá

1 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni ni ilẹ Egipti pe,

2 Oṣù yi ni yio ṣe akọ́kà oṣù fun nyin: on ni yio ṣe ekini oṣù ọdún fun nyin.

3 Ẹ sọ fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli pe, Ni ijọ́ kẹwa oṣù yi ni ki olukuluku wọn ki o mú ọdọ-agutan sọdọ, gẹgẹ bi ile baba wọn, ọdọ-agutan kan fun ile kan:

4 Bi awọn ara ile na ba si kere jù ìwọn ọdọ-agutan na lọ, ki on ati aladugbo rẹ̀ ti o sunmọ-eti ile rẹ̀, ki o mú gẹgẹ bi iye awọn ọkàn na, olukuluku ni ìwọn ijẹ rẹ̀ ni ki ẹ ṣiro ọdọ-agutan na.

5 Ailabùku ni ki ọdọ-agutan nyin ki o jẹ́, akọ ọlọdún kan: ẹnyin o mú u ninu agutan, tabi ninu ewurẹ:

6 Ẹnyin o si fi i pamọ́ titi o fi di ijọ́ kẹrinla oṣù na: gbogbo agbajọ ijọ Israeli ni yio pa a li aṣalẹ.

7 Nwọn o si mú ninu ẹ̀jẹ na, nwọn o si fi tọ́ ara opó ìha mejeji, ati sara atẹrigba ile wọnni, ninu eyiti nwọn o jẹ ẹ.

8 Nwọn o si jẹ ẹran na ti a fi iná sun li oru na, ati àkara alaiwu; ewebẹ kikorò ni nwọn o fi jẹ ẹ.

9 Ẹ máṣe jẹ ninu rẹ̀ ni tutù, tabi ti a fi omi bọ̀, bikoṣepe sisun ninu iná; ati ori rẹ̀, ati itan rẹ̀, ati akopọ̀ inu rẹ̀ pẹlu.

10 Ẹ kò si gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rẹ̀ dé ojumọ́; eyiti o ba si kù di ijọ́ keji on ni ki ẹnyin ki o daná sun.

11 Bayi li ẹnyin o si jẹ ẹ; ti ẹnyin ti àmure didì li ẹgbẹ nyin, bàta nyin li ẹsẹ̀ nyin, ati ọpá nyin li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si yara jẹ ẹ: irekọja OLUWA ni.

12 Nitoriti emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ti ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA.

13 Ẹ̀jẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹ̀jẹ na, emi o ré nyin kọja, iyọnu na ki yio wá sori nyin lati run nyin nigbati mo ba kọlù ilẹ Egipti.

14 Ọjọ́ oni ni yio si ma ṣe ọjọ́ iranti fun nyin, ẹnyin o si ma ṣe e li ajọ fun OLUWA ni iran-iran nyin, ẹ o si ma ṣe e li ajọ nipa ìlana lailai.

Àjọ̀dún Àìwúkàrà

15 Ijọ́ meje li ẹ o fi ma jẹ àkara alaiwu; li ọjọ́ kini gan li ẹ o palẹ iwukàra mọ́ kuro ni ile nyin; nitori ẹniti o ba jẹ àkara wiwu lati ọjọ́ kini lọ titi o fi di ọjọ́ keje, ọkàn na li a o ke kuro ninu Israeli.

16 Ati li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà, ati li ọjọ́ keje apejọ mimọ́ yio wà fun nyin; a ki yio ṣe iṣẹkiṣẹ ninu wọn, bikoṣe eyiti olukuluku yio jẹ, kìki eyinì li a le ṣe ninu nyin.

17 Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai.

18 Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ.

19 Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na.

20 Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.

Àjọ Ìrékọjá Kinni

21 Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na.

22 Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀.

23 Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.

24 Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai.

25 O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi.

26 Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi?

27 Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn.

28 Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.

Ikú Àwọn Àkọ́bí

29 O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin.

30 Farao si dide li oru, on ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ara Egipti; igbe nla si ta ni Egipti; nitoriti kò si ile kan ti enia kan kò kú.

31 O si pè Mose on Aaroni li oru, o si wipe, Ẹ dide, ki ẹ jade lọ kuro lãrin awọn enia mi, ati ẹnyin ati awọn ọmọ Israeli; ki ẹ si lọ sìn OLUWA, bi ẹ ti wi.

32 Ẹ si mú agbo nyin ati ọwọ́-ẹran nyin, bi ẹ ti wi, ki ẹ si ma lọ; ki ẹ si sure fun mi pẹlu.

33 Awọn ara Egipti si nrọ̀ awọn enia na, ki nwọn ki o le rán wọn jade lọ kuro ni ilẹ na kánkan; nitoriti nwọn wipe, Gbogbo wa di okú.

34 Awọn enia na si mú iyẹfun pipò wọn ki nwọn ki o to fi iwukàra si i, a si dì ọpọ́n ìpo-iyẹfun wọn sinu aṣọ wọn lé ejika wọn.

35 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; nwọn si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ lọwọ awọn ara Egipti.

36 OLUWA si fun awọn enia na li ojurere li oju awọn ara Egipti, bẹ̃ni nwọn si fun wọn li ohun ti nwọn bère. Nwọn si kó ẹrù awọn ara Egipti.

37 Awọn ọmọ Israeli si rìn lati Ramesesi lọ si Sukkotu, nwọn to ìwọn ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀ ọkunrin, li àika ọmọde.

38 Ati ọ̀pọ enia ti o dàpọ mọ́ wọn bá wọn goke lọ pẹlu; ati agbo, ati ọwọ́-ẹran, ani ọ̀pọlọpọ ẹran.

39 Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn.

40 Njẹ ìgba atipo awọn ọmọ Israeli ti nwọn ṣe ni ilẹ Egipti, o jẹ́ irinwo ọdún o le ọgbọ̀n.

41 O si ṣe li opin irinwo ọdún o le ọgbọ̀n, ani li ọjọ́ na gan, li o si ṣe ti gbogbo ogun OLUWA jade kuro ni ilẹ Egipti.

42 Oru ti a ikiyesi ni gidigidi si OLUWA ni mimú wọn jade kuro ni ilẹ Egipti: eyi li oru ti a ikiyesi si OLUWA, li ati irandiran gbogbo awọn ọmọ Israeli.

43 OLUWA si wi fun Mose ati Aaroni pe, Eyi ni ìlana irekọja: alejokalejò ki yio jẹ ninu rẹ̀:

44 Ṣugbọn iranṣẹ ẹnikẹni ti a fi owo rà, nigbati iwọ ba kọ ọ nilà, nigbana ni ki o jẹ ninu rẹ̀.

45 Alejò ati alagbaṣe ki yio jẹ ninu rẹ̀.

46 Ni ile kan li a o jẹ ẹ; iwọ kò gbọdọ mú ninu ẹran rẹ̀ jade sode kuro ninu ile na; bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọ́ ọkan ninu egungun rẹ̀.

47 Gbogbo ijọ Israeli ni yio ṣe e.

48 Nigbati alejò kan ba nṣe atipo lọdọ rẹ, ti o si nṣe ajọ irekọja si OLUWA, ki a kọ gbogbo ọkunrin rẹ̀ nilà, nigbana ni ki ẹ jẹ ki o sunmọtosi, ki o si ṣe e; on o si dabi ẹniti a bi ni ilẹ na: nitoriti kò si ẹni alaikọlà ti yio jẹ ninu rẹ̀.

49 Ofin kan ni fun ibilẹ ati fun alejò ti o ṣe atipo ninu nyin.

50 Bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ṣe; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.

51 O si ṣe li ọjọ́ na gan, OLUWA mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.