Eks 28 YCE

1 IWỌ si mú Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀ si ọdọ rẹ, kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi, ani Aaroni, Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni.

2 Iwọ o si dá aṣọ mimọ́ fun Aaroni arakunrin rẹ fun ogo ati fun ọṣọ́.

3 Iwọ o si sọ fun gbogbo awọn ti o ṣe amoye, awọn ẹniti mo fi ẹmi ọgbọ́n kún, ki nwọn ki o le dá aṣọ Aaroni lati yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

4 Wọnyi si li aṣọ ti nwọn o dá; igbàiya kan, ati ẹ̀wu-efodi, ati aṣọ igunwà, ati ẹ̀wu-awọtẹlẹ ọlọnà, fila, ati ọjá-amure: nwọn o si dá aṣọ mimọ́ wọnyi fun Aaroni arakunrin rẹ, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

5 Nwọn o si mú wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ.

6 Nwọn o si ṣe ẹ̀wu-efodi ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ti ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ iṣẹ ọlọnà,

7 Yio ní aṣọ ejika meji ti o solù li eti rẹ̀ mejeji; bẹ̃ni ki a so o pọ̀.

8 Ati onirũru-ọnà ọjá rẹ̀, ti o wà lori rẹ̀ yio ri bakanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

9 Iwọ o si mú okuta oniki meji, iwọ o si fin orukọ awọn ọmọ Israeli sara wọn:

10 Orukọ awọn mẹfa sara okuta kan, ati orukọ mẹfa iyokù sara okuta keji, gẹgẹ bi ìbí wọn.

11 Iṣẹ-ọnà afin-okuta, bi ifin èdidi-àmi, ni iwọ o fin okuta mejeji gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli: iwọ o si dè wọn si oju-ìde wurà.

12 Iwọ o si fi okuta mejeji si ejika ẹ̀wu-efodu na, li okuta iranti fun awọn ọmọ Israeli; Aaroni yio si ma rù orukọ wọn niwaju OLUWA li ejika rẹ̀ mejeji fun iranti.

13 Iwọ o si ṣe oju-ìde wurà:

14 Ati okùn ẹ̀wọn meji ti kìki wurà; iṣẹ ọnà-lilọ ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ki iwọ ki o si so okùn ẹ̀wọn iṣẹ ọnà-lilọ ni si oju-ìde na.

15 Iwọ o si fi iṣẹ ọgbọ́n na ṣe igbàiya idajọ na; nipa iṣẹ-ọnà ẹ̀wu-efodi ni iwọ o ṣe e; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododò, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ni iwọ o fi ṣe e.

16 Iha mẹrin ọgbọgba ni ki iwọ ki o ṣe e ni iṣẹpo meji; ika kan ni ìna rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀.

17 Iwọ o si tò ìto okuta sinu rẹ̀, ẹsẹ̀ okuta mẹrin: ẹsẹ̀ kini, sardiu, topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini:

18 Ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi;

19 Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu;

20 Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, ati oniki, ati jasperi: a o si tò wọn si oju wurà ni didè wọn.

21 Okuta wọnni yio si wà gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn; bi ifin edidi-àmi; olukuluku gẹgẹ bi orukọ rẹ̀ ni nwọn o wà fun ẹ̀ya Israeli mejejila.

22 Iwọ o si ṣe okùn ẹ̀wọn kìka wurà iṣẹ ọnà-lilọ si igbàiya na.

23 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji sara igbàiya na, iwọ o si fi oruka meji na si eti mejeji igbàiya na.

24 Iwọ o si fi okùn ẹ̀wọn wurà mejeji sinu oruka meji wọnni li eti igbàiya na.

25 Ati eti ẹ̀wọn meji ni ki iwọ ki o so mọ́ oju-ìde mejeji, ki o si fi si ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀.

26 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si eti mejeji igbàiya na li eti rẹ̀, ti o wà ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inú.

27 Iwọ o si ṣe oruka wurà meji, iwọ o si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi mejeji nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ti o kọjusi isolù rẹ̀, loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na.

28 Nwọn o si fi oruka rẹ̀ so igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi na ti on ti ọjá àwọn alaró, ki o le wà loke onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ki a má si ṣe tú igbàiya na kuro lara ẹ̀wu-efodi na.

29 Aaroni yio si ma rù orukọ awọn ọmọ Israeli ninu igbàiya idajọ li àiya rẹ̀, nigbati o ba nwọ̀ ibi mimọ́ nì lọ, fun iranti nigbagbogbo niwaju OLUWA.

30 Iwọ o si fi Urimu on Tummimu sinu igbàiya idajọ; nwọn o si wà li àiya Aaroni, nigbati o ba nwọle lọ niwaju OLUWA; Aaroni yio si ma rù idajọ awọn ọmọ Israeli li àiya rẹ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA.

31 Iwọ o si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni kìki aṣọ-alaró.

32 Oju ọrùn yio si wà lãrin rẹ̀ fun ori; ọjá iṣẹti yio si wà yi oju rẹ̀ ká, iṣẹ-oniṣọnà gẹgẹ bi ẹ̀wu ogun, ki o má ba fàya.

33 Ati ni iṣẹti rẹ̀ nisalẹ ni iwọ o ṣe pomegranate aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, yi iṣẹti rẹ̀ ká; ati ṣaworo wurà lãrin wọn yiká;

34 Ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, li eti iṣẹti aṣọ igunwa na yiká.

35 On o si wà lara Aaroni lati ma fi ṣiṣẹ: a o si ma gbọ́ iró rẹ̀ nigbati o ba wọ̀ ibi mimọ́ lọ niwaju OLUWA, ati nigbati o ba si njade bọ̀, ki o má ba kú.

36 Iwọ o si ṣe awo ni kìki wurà, iwọ o si fin sara rẹ̀, gẹgẹ bi fifin èdidi-àmi pe, MIMỌ́ SI OLUWA.

37 Iwọ o si fi i sara ọjá-àwọn alaró, ki o le ma wà lara fila nì, niwaju fila na ni ki o wà.

38 On o si ma wà niwaju ori Aaroni, ki Aaroni le ma rù ẹ̀ṣẹ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yio si yàsimimọ́, ninu gbogbo ẹ̀bun mimọ́ wọn: on o si ma wà niwaju ori rẹ̀ nigbagbogbo, ki OLUWA ki o le ni inudidùn si wọn.

39 Iwọ o si fi ọ̀gbọ didara wun ẹ̀wu-awọtẹlẹ, iwọ o si fi ọ̀gbọ didara ṣe fila, iwọ o si fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe ọjá-amure.

40 Iwọ o si dá ẹ̀wu-awọtẹlẹ fun awọn ọmọ Aaroni, iwọ o si dá ọjá-amure fun wọn, iwọ o si dá fila fun wọn, fun ogo ati fun ọṣọ́.

41 Iwọ o si fi wọn wọ̀ Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; iwọ o si ta oróro si wọn li ori, iwọ o si yà wọn simimọ́, iwọ o si sọ wọn di mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

42 Iwọ o si dá ṣòkoto ọ̀gbọ fun wọn lati ma fi bò ìhoho wọn, ki o ti ibadi dé itan:

43 Nwọn o si wà lara Aaroni, ati lara awọn ọmọ rẹ̀, nigbati nwọn ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ, lati ṣiṣẹ ni ibi mimọ́; ki nwọn ki o má ba dẹ̀ṣẹ, nwọn a si kú: ìlana lailai ni fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.