1 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide, gòke lati ihin lọ, iwọ ati awọn enia na ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, si ilẹ ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi i fun:
2 Emi o si rán angeli kan si iwaju rẹ; emi o si lé awọn ara Kenaani, awọn ara Amori, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi jade:
3 Si ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; emi ki yio sa gòke lọ lãrin rẹ; nitori ọlọrùn lile ni iwọ: ki emi ki o má ba run ọ li ọ̀na.
4 Nigbati awọn enia na si gbọ́ ihin buburu yi, nwọn kãnu: enia kan kò si wọ̀ ohun ọṣọ́ rẹ̀.
5 OLUWA si ti wi fun Mose pe, Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, ọlọ́rùn lile ni nyin: bi emi ba gòke wá sãrin rẹ ni iṣẹju kan, emi o si run ọ: njẹ nisisiyi bọ́ ohun ọṣọ́ rẹ kuro lara rẹ, ki emi ki o le mọ̀ ohun ti emi o fi ọ ṣe.
6 Awọn ọmọ Israeli si bọ́ ohun ọṣọ́ wọn kuro lara wọn leti oke Horebu.
7 Mose si mú agọ́ na, o si pa a lẹhin ibudó, li òkere rére si ibudó; o pè e ni Agọ́ ajọ. O si ṣe, olukuluku ẹniti mbère OLUWA o jade lọ si agọ́ ajọ, ti o wà lẹhin ibudó.
8 O si ṣe, nigbati Mose jade lọ si ibi agọ́ na, gbogbo awọn enia a si dide duro, olukuluku a si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀, a ma wò ẹhin Mose, titi yio fi dé ibi agọ́ na.
9 O si ṣe, bi Mose ti dé ibi agọ́ na, ọwọ̀n awọsanma sọkalẹ, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: OLUWA si bá Mose sọ̀rọ.
10 Gbogbo enia si ri ọwọ̀n awọsanma na o duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: gbogbo enia si dide duro, nwọn si wolẹ sìn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀.
11 OLUWA si bá Mose sọ̀rọ li ojukoju, bi enia ti ibá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ. O si tun pada lọ si ibudó: ṣugbọn Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, ọdọmọkunrin kan, kò lọ kuro ninu agọ́ na.
12 Mose si wi fun OLUWA pe, Wò o, iwọ wi fun mi pe, Mú awọn enia wọnyi gòke lọ: sibẹ̀ iwọ kò jẹ ki emi ki o mọ̀ ẹniti iwọ o rán pẹlu mi. Ṣugbọn iwọ wipe, Emi mọ̀ ọ li orukọ, iwọ si ri ore-ọfẹ li oju mi pẹlu.
13 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, fi ọ̀na rẹ hàn mi nisisiyi, ki emi ki o le mọ̀ ọ, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ: ki o si rò pe orilẹ-ède yi enia rẹ ni.
14 On si wipe, Oju mi yio ma bá ọ lọ, emi o si fun ọ ni isimi.
15 On si wi fun u pe, Bi oju rẹ kò ba bá wa lọ, máṣe mú wa gòke lati ihin lọ.
16 Nipa ewo li a o fi mọ̀ nihinyi pe, emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ani emi ati awọn enia rẹ? ki iha iṣe ni ti pe iwọ mbá wa lọ ni, bẹ̃ni a o si yà wa sọ̀tọ, emi ati awọn enia rẹ, kuro lara gbogbo enia ti o wà lori ilẹ?
17 OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o ṣe ohun yi ti iwọ sọ pẹlu: nitoriti iwọ ri ore-ọfẹ li oju mi, emi si mọ̀ ọ li orukọ.
18 O si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ogo rẹ̀ hàn mi.
19 On si wi fun u pe, Emi o mu gbogbo ore mi kọja niwaju rẹ, emi o si pè orukọ OLUWA niwaju rẹ; emi o si ṣe ore-ọfẹ fun ẹniti emi nfẹ ṣe ore-ọfẹ fun, emi o si ṣe ãnu fun ẹniti emi o ṣe ãnu fun.
20 On si wipe, Iwọ kò le ri oju mi: nitoriti kò sí enia kan ti iri mi, ti si yè.
21 OLUWA si wipe, Wò, ibi kan wà lẹba ọdọ mi, iwọ o si duro lori apata:
22 Yio si ṣe, nigbati ogo mi ba nrekọja, emi o fi ọ sinu palapala apata, emi o si fi ọwọ́ mi bò ọ titi emi o fi rekọja:
23 Nigbati emi o mú ọwọ́ mi kuro, iwọ o si ri akẹhinsi mi: ṣugbọn oju mi li a ki iri.