Eks 20 YCE

1 ỌLỌRUN si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi pe,

2 Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ jade lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá.

3 Iwọ kò gbọdọ lí Ọlọrun miran pẹlu mi.

4 Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ̀ ilẹ.

5 Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi;

6 Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si npa ofin mi mọ́.

7 Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pè orukọ rẹ̀ lasan bi alailẹ̀ṣẹ li ọrùn.

8 Ranti ọjọ́ isimi, lati yà a simimọ́.

9 Ọjọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo:

10 Ṣugbọn ọjọ́ keje li ijọ́ isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ohunọ̀sin rẹ, ati alejò rẹ̀ ti mbẹ ninu ibode rẹ:

11 Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́.

12 Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.

13 Iwọ kò gbọdọ pania.

14 Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga.

15 Iwọ kò gbọdọ jale.

16 Iwọ kò gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ.

17 Iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, tabi ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ.

18 Gbogbo awọn enia na si ri ãrá na, ati mànamána na, ati ohùn ipè na, nwọn ri oke na nṣe ẽfi: nigbati awọn enia si ri i, nwọn ṣí, nwọn duro li òkere rére.

19 Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma bá wa sọ̀rọ̀, awa o si gbọ́: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o bá wa sọ̀rọ, ki awa ki o má ba kú.

20 Mose si wi fun awọn enia pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitoriti Ọlọrun wá lati dan nyin wò, ati ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o le ma wà li oju nyin, ki ẹnyin ki o máṣe ṣẹ̀.

21 Awọn enia si duro li òkere rére, Mose si sunmọ ibi òkunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbé wà.

22 OLUWA si wi fun Mose pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin ri bi emi ti bá nyin sọ̀rọ lati ọrun wá.

23 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun miran pẹlu mi; Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun fadaka, tabi ọlọrun wurà, fun ara nyin.

24 Pẹpẹ erupẹ ni ki iwọ mọ fun mi, lori rẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, ati ẹbọ alafia rẹ, agutan rẹ, ati akọmalu rẹ: ni ibi gbogbo ti mo ba gbé fi iranti orukọ mi si, emi o ma tọ̀ ọ wá, emi o si ma bukún fun ọ.

25 Bi iwọ o ba si mọ pẹpẹ okuta fun mi, iwọ kò gbọdọ fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: nitori bi iwọ ba gbé ohun-ọnà rẹ lé ori rẹ̀, iwọ sọ ọ di aimọ́.

26 Iwọ kò si gbọdọ ba àkasọ gùn ori pẹpẹ mi, ki ìhoho rẹ ki o máṣe hàn lori rẹ̀.