2 Wi nisisiyi li eti awọn enia wọnyi, ki olukuluku ọkunrin ki o bère lọdọ aladugbo rẹ̀ ati olukuluku obinrin lọdọ aladugbo rẹ̀, ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà.
3 OLUWA si fi ojurere fun awọn enia na li oju awọn ara Egipti. Pẹlupẹlu Mose ọkunrin nì o pọ̀ gidigidi ni ilẹ Egipti, li oju awọn iranṣẹ Farao, ati li oju awọn enia na.
4 Mose si wipe, Bayi li OLUWA wi, Lãrin ọganjọ li emi o jade lọ sãrin Egipti:
5 Gbogbo awọn akọ́bi ti o wà ni ilẹ Egipti ni yio si kú, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀, titi yio si fi dé akọ́bi iranṣẹbinrin ti o wà lẹhin ọlọ; ati gbogbo akọ́bi ẹran.
6 Ẹkún nla yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, eyiti irú rẹ̀ kò si ri, ti ki yio si si irú rẹ̀ mọ́.
7 Ṣugbọn si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli li ajá ki yio yọ ahọn rẹ̀, si enia tabi si ẹran: ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi OLUWA ti fi ìyatọ sãrin awọn ara Egipti ati Israeli.
8 Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ni yio si sọkalẹ tọ̀ mi wá, ti nwọn o si fori wọn balẹ fun mi pe, Iwọ jade lọ ati gbogbo awọn enia ẹhin rẹ: lẹhin ìgba na li emi o to jade. O si jade kuro niwaju Farao ni ibinu nla.