1 OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni ni ilẹ Egipti pe,
2 Oṣù yi ni yio ṣe akọ́kà oṣù fun nyin: on ni yio ṣe ekini oṣù ọdún fun nyin.
3 Ẹ sọ fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli pe, Ni ijọ́ kẹwa oṣù yi ni ki olukuluku wọn ki o mú ọdọ-agutan sọdọ, gẹgẹ bi ile baba wọn, ọdọ-agutan kan fun ile kan:
4 Bi awọn ara ile na ba si kere jù ìwọn ọdọ-agutan na lọ, ki on ati aladugbo rẹ̀ ti o sunmọ-eti ile rẹ̀, ki o mú gẹgẹ bi iye awọn ọkàn na, olukuluku ni ìwọn ijẹ rẹ̀ ni ki ẹ ṣiro ọdọ-agutan na.
5 Ailabùku ni ki ọdọ-agutan nyin ki o jẹ́, akọ ọlọdún kan: ẹnyin o mú u ninu agutan, tabi ninu ewurẹ:
6 Ẹnyin o si fi i pamọ́ titi o fi di ijọ́ kẹrinla oṣù na: gbogbo agbajọ ijọ Israeli ni yio pa a li aṣalẹ.