15 Ijọ́ meje li ẹ o fi ma jẹ àkara alaiwu; li ọjọ́ kini gan li ẹ o palẹ iwukàra mọ́ kuro ni ile nyin; nitori ẹniti o ba jẹ àkara wiwu lati ọjọ́ kini lọ titi o fi di ọjọ́ keje, ọkàn na li a o ke kuro ninu Israeli.
16 Ati li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà, ati li ọjọ́ keje apejọ mimọ́ yio wà fun nyin; a ki yio ṣe iṣẹkiṣẹ ninu wọn, bikoṣe eyiti olukuluku yio jẹ, kìki eyinì li a le ṣe ninu nyin.
17 Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai.
18 Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ.
19 Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na.
20 Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.
21 Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na.