19 Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na.
20 Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.
21 Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na.
22 Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀.
23 Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.
24 Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai.
25 O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi.