22 Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀.
23 Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.
24 Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai.
25 O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi.
26 Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi?
27 Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn.
28 Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.