23 Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin.
24 Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai.
25 O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi.
26 Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi?
27 Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn.
28 Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.
29 O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin.