29 O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin.
30 Farao si dide li oru, on ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ara Egipti; igbe nla si ta ni Egipti; nitoriti kò si ile kan ti enia kan kò kú.
31 O si pè Mose on Aaroni li oru, o si wipe, Ẹ dide, ki ẹ jade lọ kuro lãrin awọn enia mi, ati ẹnyin ati awọn ọmọ Israeli; ki ẹ si lọ sìn OLUWA, bi ẹ ti wi.
32 Ẹ si mú agbo nyin ati ọwọ́-ẹran nyin, bi ẹ ti wi, ki ẹ si ma lọ; ki ẹ si sure fun mi pẹlu.
33 Awọn ara Egipti si nrọ̀ awọn enia na, ki nwọn ki o le rán wọn jade lọ kuro ni ilẹ na kánkan; nitoriti nwọn wipe, Gbogbo wa di okú.
34 Awọn enia na si mú iyẹfun pipò wọn ki nwọn ki o to fi iwukàra si i, a si dì ọpọ́n ìpo-iyẹfun wọn sinu aṣọ wọn lé ejika wọn.
35 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; nwọn si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ lọwọ awọn ara Egipti.